Judges 4:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA mú ìdàrúdàpọ̀ bá Sisera ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ níwájú Baraki. Bí àwọn ọmọ ogun Baraki ti ń fi idà pa wọ́n, Sisera sọ̀kalẹ̀ ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si fi oju idà ṣẹgun Sisera, ati gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun rẹ̀, niwaju Baraki; Sisera si sọkalẹ kuro li ori kẹkẹ́ rẹ̀, o si fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sálọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì mú ìdàrúdàpọ̀ wá sí àárin ogun Sísérà, OLÚWA sì fi ojú idà ṣẹ́gun Sísérà àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun àti ọmọ ogun orí ilẹ̀ ní iwájú Bárákì. Sísérà sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ó sì fi ẹṣẹ̀ sálọ.