Judges 4:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Baraki lépa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun Sisera títí dé Haroṣeti-ha-goimu, wọ́n sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun Sisera láìku ẹyọ ẹnìkan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Baraki lepa awọn kẹkẹ́, ati ogun na, titi dé Haroṣeti awọn orilẹ-ède: gbogbo ogun Sisera si ti oju idà ṣubu; ọkunrin kanṣoṣo kò si kù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bárákì àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀ èdè, títí ó fi pa gbogbo àwọn ọmọ ogun Ṣísérà kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láàyè.