Judges 4:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Sisera sá lọ sí àgọ́ Jaeli, aya Heberi, ará Keni, nítorí pé alaafia wà ní ààrin Jabini, ọba Hasori, ati ìdílé Heberi ará Keni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Sisera ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sálọ si agọ́ Jaeli aya Heberi ọmọ Keni: nitoriti alafia wà lãrin Jabini ọba Hasori ati ile Heberi ọmọ Keni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Ṣísérà ti fi ẹṣẹ̀ sá lọ sí àgọ́ Jáélìa aya Hébérì ẹ̀yà Kénì: nítorí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àlàáfíà wà láàárin Jábínì ọba Háṣórì àti ìdílé Hébérì ti ẹ̀yà Kénì.