Judges 4:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ti rẹ Sisera tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi sùn lọ fọnfọn. Jaeli bá mú òòlù kan, ati èèkàn àgọ́, ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí Sisera sùn sí, ó kan èèkàn náà mọ́ ọn lẹ́bàá etí títí tí èèkàn náà fi wọlé, ó sì kú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Jaeli aya Heberi mú iṣo-agọ́ kan, o si mú õlù li ọwọ́ rẹ̀, o si yọ́ tọ̀ ọ, o si kàn iṣo na mọ́ ẹbati rẹ̀, o si wọ̀ ilẹ ṣinṣin; nitoriti o sùn fọnfọn; bẹ̃ni o daku, o si kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Jáélì ìyàwó Hébérì mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó ṣùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin ó sì kú.