Judges 4:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli bá tún ké pe OLUWA pé kí ó ran àwọn lọ́wọ́, nítorí pé ẹẹdẹgbẹrun (900) ni kẹ̀kẹ́ ogun Jabini tí wọ́n fi irin ṣe; ó sì ni wọ́n lára fún ogún ọdún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA: nitoriti o ní ẹdẹgbẹrun kẹkẹ́ irin; ogun ọdún li o si fi pọ́n awọn ọmọ Israeli loju gidigidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Ísírẹ́lì lójú gidigidi fún ogún ọdún. Ísírẹ́lì ké pe OLÚWA fún ìrànlọ́wọ́.