Judges 4:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lábẹ́ ọ̀pẹ kan, tí wọ́n sọ ní ọ̀pẹ Debora, tí ó wà láàrin Rama ati Bẹtẹli ní agbègbè olókè ti Efuraimu ní í máa ń jókòó sí, ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli tií máa ń lọ bá a fún ìdájọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si ngbé abẹ igi-ọpẹ Debora li agbedemeji Rama ati Beti-eli ni ilẹ òke Efraimu: awọn ọmọ Israeli a si ma wá sọdọ rẹ̀ fun idajọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a ṣọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Dèbórà láàárin Rámà àti Bẹ́tẹ́lì ní ilẹ̀ òkè Éfúráímù, àwọn ará Ísírẹ́lì a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn OLÚWA láti ẹnu rẹ̀.