Judges 5:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n gbéra láti Efuraimu lọ sí àfonífojì náà, wọ́n tẹ̀lé ọ, ìwọ Bẹnjamini pẹlu àwọn eniyan rẹ. Àwọn ọ̀gágun wá láti Makiri, àwọn olórí ogun sì wá láti Sebuluni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati Efraimu ni nwọn ti wá awọn ti gbongbo wọn wà ni Amaleki; lẹhin rẹ, Benjamini, lãrin awọn enia rẹ; lati Makiri ni awọn alaṣẹ ti sọkalẹ wá, ati lati Sebuluni li awọn ẹniti nmú ọ̀pá-oyè lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn kan jáde wá láti Éfúráímù, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Ámélékì; Bẹ́ńjámínì wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ. Láti Mákírì ni àwọn alásẹ ti sọ̀ kalẹ̀ wá, láti Ṣébúlúnì ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́.