Judges 5:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ìjòyè Isakari náà bá Debora wá, àwọn ọmọ Isakari jẹ́ olóòótọ́ sí Baraki, wọ́n sì dà tẹ̀lé e lẹ́yìn lọ sí àfonífojì. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì, ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ-alade Issakari wà pẹlu Debora; bi Issakari ti ri, bẹ̃ni Baraki; nwọn sure li ẹsẹ̀ lọ si afonifoji na. Ni ipadò Reubeni ni ìgbero pupọ̀ wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ aládé Ísákárì wá pẹ̀lú Dèbórà; bẹ́è ni, Ísákàrì wà pẹ̀lú Bárákì, wọ́n fi ẹṣẹ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà. Ní ipadò Rúbẹ́nì ni ìgbèrò púpọ̀ wà.