Judges 5:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Angẹli OLUWA ní, “Ìlú ègún ni ìlú Merosi, ẹni ègún burúkú sì ni àwọn olùgbé rẹ̀, nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò wá ran OLUWA lọ́wọ́; wọn kò ran OLUWA lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn alágbára.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ fi Merosi bú, bẹ̃li angeli OLUWA wi, ẹ fi awọn ara inu rẹ̀ bú ibú kikorò; nitoriti nwọn kò wá si iranlọwọ OLUWA, si iranlọwọ OLUWA si awọn alagbara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Ẹ fi Mérósì,’ bú ni ańgẹ́lì OLÚWA wí. ‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ gégùn ún kíkorò, nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ OLÚWÁ, láti dojúkọ àwọn alágbára.’