Judges 5:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìyá Sisera ń yọjú láti ojú fèrèsé, ó bẹ̀rẹ̀ sí wo ọ̀nà láti ibi ihò fèrèsé. Ó ní, “Kí ló dé tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí wọ́n tó dé? Kí ló dé tí ó fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí á tó gbúròó ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin tí wọ́n ń wọ́ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iya Sisera nwò oju-ferese, o si kigbe, o kigbe li oju-ferese ọlọnà pe; Ẽṣe ti kẹkẹ́ rẹ̀ fi pẹ bẹ̃ lati dé? Ẽṣe ti ẹsẹ̀ kẹkẹ̀ rẹ̀ fi duro lẹhin?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìyá Ṣísérà yọjú láti ojú fèrèsé, ó sì kígbe, ó kígbe ní ojú fèrèsé ọlọ́nà pé, ‘Èése tí kẹ̀kẹ́ ẹsin rẹ fi pẹ́ bẹ́ẹ̀ láti dé? Èéṣe tí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ẹsin rẹ̀ fí dúró lẹ́yìn?’