Judges 5:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ṣebí ìkógun ni wọ́n ń wá, tí wọ́n sì ń pín? Obinrin kan tabi meji fún ọkunrin kọ̀ọ̀kan, ìkógun àwọn aṣọ aláró fún Sisera, ìkógun àwọn aṣọ aláró tí wọ́n dárà sí lára, aṣọ ìborùn aláró meji tí wọ́n dárà sí lára fún èmi náà?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kò ha ti ri, nwọn kò ha ti pín ikogun bi? fun olukuluku ọkunrin wundia kan tabi meji; fun Sisera ikogun-aṣọ alarabara, ikógun-aṣọ alarabara oniṣẹ-abẹ́rẹ, aṣọ alarabara oniṣẹ-abẹ́rẹ ni ìha mejeji, li ọrùn awọn ti a kó li ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Wọn kò ha ti rí wọn, wọn kò ha ti pín ìkógun bọ̀ fún olúkálùkù: ọmọbìnrin kan tàbí méjì fún ọkùnrin kan, fún Ṣísérà ìkógun aṣọ aláràbarà, ìkógun aṣọ aláràbarà àti ọlọ́nà, àwọn aṣọ ọlọ́nà iyebíye fún ọrùn mi, gbogbo wọn tí a kó ní ogun?’