Judges 5:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ṣègbé, OLUWA; ṣugbọn bí oòrùn ti máa ń fi agbára rẹ̀ ràn, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa tàn. Ilẹ̀ náà sì wà ní alaafia fún ogoji ọdún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni ki o jẹ ki gbogbo awọn ọtá rẹ ki o ṣegbé OLUWA: ṣugbọn jẹ ki awọn ẹniti o fẹ́ ẹ ki o dabi õrùn nigbati o ba yọ ninu agbara rẹ̀. Ilẹ na si simi li ogoji ọdún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ kí ó ṣègbé OLÚWA! Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn. nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.” Ilẹ̀ náà sì simi ní ogójì ọdún