Judges 6:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Midiani lágbára ju àwọn ọmọ Israẹli lọ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli fi ṣe ibi tí wọn ń sápamọ́ sí lórí àwọn òkè, ninu ihò àpáta, ati ibi ààbò mìíràn ninu òkè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọwọ́ Midiani si le si Israeli: ati nitori Midiani awọn ọmọ Israeli wà ihò wọnni fun ara wọn, ti o wà ninu òke, ati ninu ọgbun, ati ni ibi-agbara wọnni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Agbára àwọn ará Mídíánì sì pọ̀ púpọ̀ lórí àwọn Ísírẹ́lì, wọ́n sì hùwà ipá sí wọn, nítorí ìdí èyí, àwọn Ísírẹ́lì sá lọ sí àwọn orí òkè, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn nínú ihò àpáta, àti nínú ọ̀gbun àti ní ibi agbára nínú àpáta.