Judges 6:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Angẹli OLUWA náà bá na ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi ṣóńṣó orí rẹ̀ kan ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà; iná bá ṣẹ́ lára àpáta, ó sì jó ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà. Angẹli OLUWA náà bá rá mọ́ ọn lójú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni angeli OLUWA nà ọpá ti o wà li ọwọ rẹ̀, o si fi ori rẹ̀ kàn ẹran na ati àkara alaiwu na; iná si là lati inu okuta na jade, o si jó ẹran na, ati àkara alaiwu; angeli OLUWA na si lọ kuro niwaju rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ańgẹ́lì OLÚWA sì fi orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ kan ẹran àti àkàrà àìwú náà. Iná sì jáde láti inú àpáta, ó sì jó ẹran àti àkàrà náà, kò sì rí ańgẹ́lì náà mọ́.