Judges 6:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí o wá tẹ́ pẹpẹ kan fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ lórí òkítì ibi gegele náà. To àwọn òkúta rẹ̀ lérí ara wọn dáradára, lẹ́yìn náà mú akọ mààlúù keji kí o sì fi rú ẹbọ sísun. Igi ère oriṣa Aṣera tí o bá gé lulẹ̀ ni kí o fi ṣe igi ẹbọ sísun náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ lori ibi agbara yi, bi o ti yẹ, ki o si mú akọ-malu keji, ki o si fi igi-oriṣa ti iwọ bẹ́ lulẹ ru ẹbọ sisun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn èyí kí o wá mọ pẹpẹ èyí tí ó yẹ fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ lórí òkè yìí. Kí o lọ́ igi Áṣírà tí o ké lulẹ̀, kí o fi akọ màlúù kejì rú ẹbọ sísun sí OLÚWA.