Judges 6:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gideoni mú mẹ́wàá ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì ṣe bí OLUWA ti ní kí ó ṣe, ṣugbọn kò lè ṣe é lọ́sàn-án, nítorí ẹ̀rù àwọn ará ilé ati àwọn ará ìlú rẹ̀ ń bà á, nítorí náà lóru ni ó ṣe é.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Gideoni mú ọkunrin mẹwa ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, o si ṣe bi OLUWA ti sọ fun u: o si ṣe, nitoripe o bẹ̀ru ile baba rẹ̀ ati awọn ọkunrin ilu na, tobẹ̃ ti kò fi le ṣe e li ọsán, ti o si fi ṣe e li oru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gídíónì mú mẹ́wàá nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe bí OLÚWA ti pàṣẹ fún un ṣùgbọ́n, nítorí ó bẹ̀rù àwọn ará ilé bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ìlú náà kò ṣe é ní ọ̀sán, òru ni ó ṣe.