Judges 6:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ará ìlú náà jí ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n rí i pé, wọ́n ti wó pẹpẹ oriṣa Baali lulẹ̀, wọ́n sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ati pé wọ́n ti fi mààlúù keji rúbọ lórí pẹpẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ọkunrin ilu na si dide ni kùtukutu, si wò o, a ti wó pẹpẹ Baali lulẹ, a si bẹ́ igi-oriṣa lulẹ ti o wà lẹba rẹ̀, a si ti pa akọ-malu keji rubọ lori pẹpẹ ti a mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, tí àwọn ènìyàn ìlú náà jí, wọ́n rí i pé àti fọ́ pẹpẹ Báálì àti pé a ti bẹ́ igi òpó Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, a sì ti fi akọ màlúù kejì rúbọ lóríi pẹpẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ.