Judges 6:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé, nígbàkúùgbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá gbin ohun ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Midiani ati àwọn ará Amaleki ati àwọn kan láti inú aṣálẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, a máa kó ara wọn jọ, wọn a lọ ṣígun bá àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, bi Israeli ba gbìn irugbìn, awọn Midiani a si gòke wá, ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn; nwọn a si gòke tọ̀ wọn wá;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìgbàkúgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ti gbin ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Mídíánì, àwọn ará Ámélékì àti àwọn ará ìlà oòrùn mìíràn yóò wá láti bá wọn jà.