Judges 6:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Joaṣi dá àwọn tí wọ́n dìde sí Gideoni lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ gbèjà oriṣa Baali ni, àbí ẹ fẹ́ dáàbò bò ó? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèjà rẹ̀, pípa ni a óo pa á kí ilẹ̀ tó mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé ọlọrun ni Baali nítòótọ́, kí ó gbèjà ara rẹ̀, nítorí pẹpẹ rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joaṣi si wi fun gbogbo awọn ti o duro tì i pe, Ẹnyin o gbèja Baali bi? tabi ẹnyin o gbà a là bi? ẹniti o ba ngbèja rẹ̀, ẹ jẹ ki a lù oluwarẹ̀ pa ni kùtukutu owurọ yi: bi on ba ṣe ọlọrun, ẹ jẹ ki o gbèja ara rẹ̀, nitoriti ẹnikan wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Jóásì bi àwọn èrò tí wọ́n fi ìbínú dúró tì í wí pé, “Ẹ̀yin yóò ha gbìjà Báálì bí? Ẹ̀yin yóò ha gbà á sílẹ̀ bí? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìjà rẹ̀ kíkú ni yóò kú ní òwúrọ̀. Bí Báálì bá ṣe Ọlọ́run ní tòótọ́ yóò jà fún ara rẹ̀ bí ẹnikẹ́ni bá wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.”