Judges 6:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti ń pe Gideoni ní Jerubaali, ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ẹ jẹ́ kí Baali bá a jà fúnra rẹ̀,” nítorí pé ó wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li ọjọ́ na, o pè orukọ rẹ̀ ni Jerubbaali, wipe, Jẹ ki Baali ki o bá a jà, nitoriti o wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ìdí èyí ní ọjọ́ náà wọ́n pe Gídíónì ní “Jérúbáálì” wí pé, “Jẹ́kí Báálì bá a jà,” nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Báálì.