Judges 6:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati àwọn ará ilẹ̀ Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn kó ara wọn jọ, wọ́n la odò Jọdani kọjá, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí àfonífojì Jesireeli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni gbogbo awọn Midiani ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn kó ara wọn jọ pọ̀; nwọn rekọja, nwọn si dó li afonifoji Jesreeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láìpẹ́ jọjọ àwọn ogun àwọn Mídíánì, ti àwọn Ámálékì àti ti àwọn ènìyàn ìhà ìlà oòrùn yóòkù kó ara wọn jọ pọ̀ ní ìṣọ̀kan, wọ́n sì kọjá Jọ́dánì wọ́n sì tẹ̀dó sí àfonífojì Jésírẹ́lì.