Judges 6:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn a gbógun tì wọ́n, wọn a sì ba gbogbo ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ náà jẹ́ títí dé agbègbè Gasa. Wọn kì í fi oúnjẹ kankan sílẹ̀ rárá ní ilẹ̀ Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fi aguntan tabi mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kankan sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn a si dótì wọn, nwọn a si run eso ilẹ na, titi iwọ o fi dé Gasa, nwọn ki isi fi onjẹ silẹ ni Israeli, tabi agutan, tabi akọ-malu, tabi kẹtẹkẹtẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò tẹ̀dó sí orí ilẹ̀ náà, wọn a sì bá irúgbìn wọ̀nyí jẹ́ títí dé Gásà, wọn kì í sì í fi ohun alààyè kankan ṣílẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kìbáà ṣe àgùntàn, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.