Judges 7:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati ti Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìlà oòrùn pọ̀ nílẹ̀ lọ bí eṣú àwọn ràkúnmí wọn kò níye, wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn Midiani ati awọn Amaleki, ati gbogbo awọn ọmọ ìha ìla-õrùn tò lọ titi li afonifoji gẹgẹ bi eṣú li ọ̀pọlọpọ; ibakasiẹ wọn kò si ní iye, bi iyanrin ti mbẹ leti okun li ọ̀pọlọpọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Mídíánì, àwọn ará Ámẹ́lẹ́kì àti gbogbo ènìyàn ìlà oòrùn tó lọ ní àfonífojì bí esú ni wọ́n rí nítorí púpọ̀ wọn. Àwọn ràkúnmí wọn kò sì lóǹkà, wọ́n sì pọ̀ bí yanrìn inú òkun.