Judges 7:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Gideoni dé ibẹ̀, ó gbọ́ tí ẹnìkan ń rọ́ àlá tí ó lá fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan pé, “Mo lá àlá kan, mo rí i tí àkàrà ọkà baali kan ré bọ́ sinu ibùdó àwọn ará Midiani. Bí ó ti bọ́ lu àgọ́ náà, ó wó o lulẹ̀, ó sì dojú rẹ̀ délẹ̀, àgọ́ náà sì tẹ́ sílẹ̀ pẹrẹsẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Gideoni si dé, kiyesi i, ọkunrin kan nrọ́ alá fun ẹnikeji rẹ̀, o si wipe, Kiyesi i, emi lá alá kan, si wò o, àkara ọkà-barle kan ṣubu si ibudó Midiani, o si bọ́ sinu agọ́ kan, o si kọlù u tobẹ̃ ti o fi ṣubu, o si doju rẹ̀ de, agọ́ na si ṣubu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gídíónì dé sí àsìkò tí ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ àlá tí ó lá sí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní, “Mo lá àlá kan, nínú àlá náà mo rí àkàrà kan tó ṣe róbótó tí a fi Báálì ṣe ń yí wọ inú ibùdó àwọn ará Mídíánì, ó sì kọlu àgọ́ pẹ̀lú agbára ńlá débi wí pé àgọ́ náà dojú dé, ó sì ṣubú.”