Judges 7:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Gideoni gbọ́ bí ó ti rọ́ àlá yìí, ati ìtumọ̀ rẹ̀, ó yin OLUWA. Ó pada sí ibùdó Israẹli, ó ní, “Ẹ dìde, nítorí OLUWA ti fi àwọn ọmọ ogun Midiani le yín lọ́wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Gideoni gbọ́ rirọ́ alá na, ati itumọ̀ rẹ̀, o tẹriba; o si pada si ibudó Israeli, o si wipe, Ẹ dide; nitoriti OLUWA ti fi ogun Midiani lé nyin lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Gídíónì gbọ́ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ sin Ọlọ́run: lẹ́yìn náà ni ó padà sí ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì pè wọ́n pé, “Ẹ dìde! Nítorí pé Ọlọ́run yóò lò yín láti ṣẹ́gun gbogbo ogun Mídíánì.”