Judges 7:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó pín àwọn ọọdunrun (300) náà sí ọ̀nà mẹta, ó fi fèrè ogun ati ìkòkò òfìfo tí wọn fi ògùṣọ̀ sí ninu lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si pín ọdunrun ọkunrin na si ẹgbẹ mẹta, o si fi ipè lé olukuluku wọn lọwọ, pẹlu ìṣa ofo, òtufu si wà ninu awọn ìṣa na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó ti pín àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì sí ọ̀nà mẹ́ta, ó fi fèrè, pẹ̀lú àwọn òfìfo ìkòkò lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́, iná sì wà nínú àwọn ìkòkò náà.