Judges 7:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gideoni ati ọgọrun-un eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá lọ sí ìkangun àgọ́ náà ní òru, nígbà tí àwọn olùṣọ́ mìíràn ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ipò àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀. Wọ́n fọn fèrè, wọ́n sì fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà lọ́wọ́ wọn mọ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Gideoni, ati ọgọrun ọkunrin ti mbẹ lọdọ rẹ̀, wá si opin ibudó, ni ibẹ̀rẹ iṣọ́ ãrin, nigbati nwọn ṣẹṣẹ yàn iṣọ́ sode: nwọn fun ipè, nwọn si fọ́ ìṣa ti o wà li ọwọ́ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gídíónì àti àwọn ọgọ́rùn-ún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé òpin ibùdó àwọn ará Mídíánì ní nǹkan bí agogo méjìlá padà. Wọ́n fun fèrè wọn, wọ́n sì tún fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà ní ọwọ́ mọ́lẹ̀.