Judges 7:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pọ̀jù fún mi, láti fi àwọn ará ilẹ̀ Midiani lé lọ́wọ́, kí àwọn ọmọ Israẹli má baà gbéraga pé agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun, wọn kò sì ní fi ògo fún mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia ti o wà lọdọ rẹ pọ̀ju fun mi lati fi awọn Midiani lé wọn lọwọ, ki Israeli ki o má ba gbé ara wọn ga si mi, pe, Ọwọ́ mi li o gbà mi là.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA wí fún Gídíónì pé, “Àwọn ọmọ ogun tí o kó jọ sọ́dọ̀ ti pọ̀ jù fún mi láti fi àwọn ogun Mídíánì lé wọn lọ́wọ́, kí Ísírẹ́lì má ba à gbé ara rẹ̀ ga sí mi wí pé agbára òun ni ó gbà á là,