Judges 7:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ẹgbẹ́ mẹtẹẹta fọn fèrè wọn, wọ́n sì fọ́ ìkòkò tì ó wà lọ́wọ́ wọn. Wọ́n fi iná ògùṣọ̀ wọn sí ọwọ́ òsì, wọ́n sì fi fèrè tí wọn ń fọn sí ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n bá pariwo pé, “Idà kan fún OLUWA ati fún Gideoni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹgbẹ mẹtẹta na si fun ipè wọn, nwọn si fọ́ ìṣa wọn, nwọn si mú awọn òtufu li ọwọ́ òsi wọn, ati ipè li ọwọ́ ọtún lati fun: nwọn si kigbe li ohùn rara pe, Idà OLUWA, ati ti Gideoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fun fèrè wọn, wọ́n tún fọ́ àwọn ìkòkò wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n mú àwọn àtùpà iná wọn ní ọwọ́ òsì wọn àti fèrè tí wọ́n ń fun ní ọwọ́ ọ̀tún wọn. Wọ́n pariwo hè è pé, “Idà kan fún OLÚWA àti fún Gídíónì!”