Judges 7:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Gideoni fọn ọọdunrun (300) fèrè wọn, Ọlọrun mú kí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá wọn dojú ìjà kọ ara wọn, gbogbo wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí apá Serera. Wọ́n sá títí dé Beti Ṣita, ati títí dé ààlà Abeli Mehola, lẹ́bàá Tabati.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin na fun ọdunrun ipè, OLUWA si yí idà olukuluku si ẹnikeji rẹ̀, ati si gbogbo ogun na: ogun na si sá titi dé Beti-ṣita ni ìha Serera, dé àgbegbe Abeli-mehola, leti Tabati.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì fun fèrè wọn, OLÚWA da ojú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan kọ ẹnìkejì rẹ̀ àti sí gbogbo ojú ọwọ́ wọn. Àwọn ọmọ ogun sì sá títí dé Bẹti Sítà ní ọ̀nà Ṣérérà títí lọ dé ìpínlẹ̀ Abeli-Méhólà ní ẹ̀bá Tábátì.