Judges 7:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gideoni rán àwọn oníṣẹ́ jákèjádò agbègbè olókè Efuraimu, ó ní, “Ẹ máa bọ̀ wá bá àwọn ará Midiani jagun, kí ẹ sì gba ojú odò lọ́wọ́ wọn títí dé Bẹtibara ati odò Jọdani.” Wọ́n pe gbogbo àwọn ọkunrin Efuraimu jáde, wọ́n sì gba gbogbo odò títí dé Bẹtibara ati odò Jọdani pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gideoni si rán onṣẹ lọ si gbogbo òke Efraimu, wipe, Ẹ sọkalẹ wá pade awọn Midiani, ki ẹ si tète gbà omi wọnni dé Beti-bara ani Jordani. Nigbana ni gbogbo awọn ọkunrin Efraimu kó ara wọn jọ, nwọn si gbà omi wọnni, titi dé Beti-bara ani Jordani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gídíónì tún ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè Éfúráímù wí pé, “Ẹ jáde wá bá àwọn ará Mídíánì jà, kí ẹ tètè gba àwọn omi Jọ́dánì títí dé Bẹti Bárà kí wọ́n tó dé bẹ̀.” Báyìí ni a ṣe pe gbogbo ọkùnrin ológun Éfúráímù jáde tí wọ́n sì gba gbogbo àwọn àbáwọdò Jọ́dánì títí dé Bẹti Bárà.