Judges 7:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n mú Orebu ati Seebu, àwọn ọmọ ọba Midiani mejeeji, wọ́n pa Orebu sí ibi òkúta Orebu, wọ́n sì pa Seebu níbi ìfúntí Seebu, bí wọ́n ti ń lé àwọn ará Midiani lọ. Wọ́n gé orí Orebu ati ti Seebu, wọ́n sì gbé wọn wá sí ọ̀dọ̀ Gideoni ní òdìkejì odò Jọdani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si mú meji ninu awọn ọmọ-alade Midiani, Orebu ati Seebu; Orebu ni nwọn si pa lori apata Orebu, ati Seebu ni nwọn si pa ni ibi-ifọnti Seebu, nwọn si lepa awọn ara Midiani, nwọn si mú ori Orebu ati Seebu wá fi fun Gideoni li apa keji odò Jordani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n mú méjì nínú àwọn olórí àwọn ará Mídíánì, àwọn náà ni Órébù àti Ṣéébù. Wọ́n pa Órébù nínú àpáta Órébù, wọ́n sì pa Ṣéébù níbi tí àwọn ènìyàn ti mọ̀ fún wáìnì tí a ń pè ní ìfúntí Ṣéébù. Wọ́n lé àwọn ará Mídíánì, nígbà tí wọ́n gbé orí Órébù àti Ṣéébù tọ Gídíónì wá ẹni tí ó wà ní ìhà kejì Jọ́dánì.