Judges 7:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA tún wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù yìí pọ̀jù sibẹsibẹ. Kó wọn lọ sí etí odò, n óo sì bá ọ dán wọn wò níbẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí mo bá wí fún ọ pé yóo lọ, òun ni yóo lọ, ẹnikẹ́ni tí mo bá sì wí fún ọ pé kò ní lọ, kò gbọdọ̀ lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia na pọ̀ju sibẹ̀; mú wọn sọkalẹ wá si odò, nibẹ̀ li emi o gbé dan wọn wò fun ọ: yio si ṣe, ẹniti mo ba wi fun ọ pe, Eyi ni yio bá ọ lọ, on na ni yio bá ọ lọ; ẹnikẹni ti mo ba si wi fun ọ pe, Eyi ki yio bá ọ lọ, on na ni ki yio si bá ọ lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì tún sọ fún Gídíónì pé, “Àwọn ènìyàn yìí sì tún pọ̀ jù. Kó wọn lọ sí ibi tí omi wà, èmi yóò sì yọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọ. Bí mo bá wí pé eléyìí yóò bá ọ lọ yóò lọ, ṣùgbọ́n tí mo bá sọ pé, ‘Eléyìí kò ní bá ọ lọ,’ òun kò gbọdọ̀ lọ.”