Judges 7:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gideoni bá gba oúnjẹ àwọn eniyan náà ati fèrè ogun wọn lọ́wọ́ wọn, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n pada sí ilé, ṣugbọn ó dá àwọn ọọdunrun (300) náà dúró. Àgọ́ àwọn ọmọ ogun Midiani wà ní àfonífojì lápá ìsàlẹ̀ ibi tí wọ́n wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia na si mu onjẹ ati ipè li ọwọ́ wọn: on si rán gbogbo Israeli lọ, olukuluku sinu agọ́ rẹ̀, o si da ọdunrun ọkunrin nì duro: ibudó Midiani si wà nisalẹ rẹ̀ li afonifoji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni Gídíónì ṣe dá àwọn Ísírẹ́lì tí ó kù padà sí àgọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó dá àwọn ọ̀ọ́dúrún ọkùnrin náà dúró. Àwọn wọ̀nyí sì gba gbogbo ohun èlò àti fèrè àwọn tí ó ti padà. Ibùdó ogun àwọn Mídíánì wà ní àfonífojì ní ìṣàlẹ̀. Ibi tí ó wà.