Judges 8:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Seba ati Salimuna wà ní ìlú Karikori pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn yòókù, gbogbo àwọn ọmọ ogun ìlà oòrùn tí wọ́n ṣẹ́kù kò ju nǹkan bí ẹẹdẹgbaajọ (15,000) lọ, nítorí pé àwọn tí wọ́n ti kú ninu àwọn ọmọ ogun wọn tí wọ́n ń lo idà tó ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ Seba ati Salmunna wà ni Karkori, ogun wọn si wà pẹlu wọn, o to ìwọn ẹdẹgbajọ ọkunrin, iye awọn ti o kù ninu gbogbo ogun awọn ọmọ ìha ìla-õrùn: nitoripe ẹgba ọgọta ọkunrin ti o lo idà ti ṣubu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àsìkò náà Ṣébà àti Ṣálímúnà wà ní Kákórì pẹ̀lú ọmọogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún (15,000) ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́ kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà oòrùn, nítorí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun.