Judges 8:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀nà èrò tí ó wà ní ìlà oòrùn Noba ati Jogibeha ni Gideoni gbà lọ, ó lọ jálu àwọn ọmọ ogun náà láì rò tẹ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gideoni si gbà ọ̀na awọn ti ngbé inú agọ́ ni ìha ìla-õrùn Noba ati Jogbeha gòke lọ, o si kọlù ogun na; nitoriti ogun na ti sọranù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gídíónì gba ọ̀nà tí àwọn dáràndáràn máa ń rìn ní apá ìhà ìlà oòrùn Nóbà àti Jógíbíà ó sì kọjú ogun sí àwọn ọmọ ogun náà nítorí wọ́n ti túra sílẹ̀.