Judges 8:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọwọ́ rẹ̀ tẹ ọdọmọkunrin ará Sukotu kan, ó sì bèèrè orúkọ àwọn olórí ati àwọn àgbààgbà ìlú Sukotu lọ́wọ́ rẹ̀. Ọdọmọkunrin yìí sì kọ orúkọ wọn sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkunrin mẹtadinlọgọrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si mú ọmọkunrin kan ninu awọn ọkunrin Sukkotu, o si bère lọwọ rẹ̀: on si ṣe apẹrẹ awọn ọmọ-alade Sukkotu fun u, ati awọn àgba ti o wà nibẹ̀, mẹtadilọgọrin ọkunrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó mú ọ̀dọ́mọkùnrin kan ará Ṣúkótì, ó sì béèrè àwọn ìbéèrè ní ọwọ́ rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì kọ orúkọ àwọn ìjòyè Ṣúkótì mẹ́tadínlọ́gọ́rin (77) fún un tí wọ́n jẹ́ àgbààgbà ìlú náà.