Judges 8:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Seba ati Salimuna bá dáhùn pé, “Ìwọ alára ni kí o dìde kí o pa wá? Ṣebí bí ọkunrin bá ṣe dàgbà sí ni yóo ṣe lágbára sí.” Gideoni bá dìde, ó pa Seba ati Salimuna, ó sì bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn ràkúnmí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Seba ati Salmunna wipe, Iwọ dide, ki o si kọlù wa: nitoripe bi ọkunrin ti ri, bẹ̃li agbara rẹ̀ ri. Gideoni si dide, o si pa Seba ati Salmunna, o si bọ́ ohun ọṣọ́ wọnni kuro li ọrùn ibakasiẹ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣébà àti Ṣálímúnà dá Gídíónì lóhùn pé, “Wá pa wá fún raàrẹ, ‘Nítorí bí ènìyàn bá ti rí bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóò rí.’ ” Gídíónì bọ́ ṣíwájú ó sì pa wọ́n, ó sì mú ohun ọ̀sọ́ tí ó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn.