Judges 8:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ìwọ̀n yẹtí wúrà tí ó gbà jẹ́ ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ṣekeli, láìka ohun ọ̀ṣọ́ ati aṣọ olówó iyebíye tí àwọn ọba Midiani wọ̀, ati àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn àwọn ràkúnmí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ìwọn oruka-etí wurà na ti o bère lọwọ wọn jẹ́ ẹdẹgbẹsan ṣekeli wurà: làika ohun ọṣọ́ wọnni, ati ohun sisorọ̀, ati aṣọ elesè-àluko ti o wà lara awọn ọba Midiani, ati li àika ẹ̀wọn ti o wà li ọrùn ibakasiẹ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ̀n òrùka wúrà tí ó bèèrè fún tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán, ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn ún méje (1700) ìwọ̀n ṣékélì èyí tó kìlógírámù mọ́kàndínlógún ààbọ̀ (19.5 kilogram), láìka àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun sísorọ̀ tí ó wà lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti aṣọ eléṣé àlùkò tí àwọn ọba Mídíánì ń wọ̀ tàbí àwọn ìlẹ̀kẹ̀ tí ó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn.