Judges 8:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀yin ni Ọlọrun fi Orebu ati Seebu, àwọn ọmọ ọba Midiani mejeeji lé lọ́wọ́. Kí ni ohun tí mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ bí ó ṣe dá wọn lóhùn, inú wọ́n yọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun sá ti fi awọn ọmọ-alade Midiani lé nyin lọwọ, Orebu ati Seebu: kini mo si le ṣe bi nyin? Nigbana ni inu wọn tutù si i, nigbati o ti wi eyinì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run ti fi Órébù àti Ṣéébù àwọn olórí àwọn ará Mídíánì lé yín lọ́wọ́. Kí ni ohun tí Móṣè ṣe tí ó tó fi wé e yín tàbí tí ó tó àṣeyọrí i yín.” Nígbà tí ó wí èyí ríru ìbínú wọn rọ lẹ̀.