Judges 9:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Igi ẹ̀gún bá dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Tí ó bá jẹ́ pé tinútinú yín ni ẹ fi fẹ́ kí n jọba yín, ẹ wá sábẹ́ ìbòòji mi, n óo sì dáàbò bò yín. Ṣugbọn bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, iná yóo yọ jáde láti ara ẹ̀gún mi, yóo sì jó igi kedari tí ó wà ní Lẹbanoni run.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Igi-ẹgún si wi fun awọn igi pe, Bi o ba ṣepe nitõtọ li ẹnyin fi emi jẹ́ ọba lori nyin, njẹ ẹ wá sá si abẹ ojiji mi: bi kò ba si ṣe bẹ̃, jẹ ki iná ki o ti inu igi-ẹgún jade wá, ki o si jó awọn igi-kedari ti Lebanoni run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Igi ẹ̀gún dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Bí lótítọ́ ni ẹ bá fẹ́ yàn mí ní ọba yín. Ẹ sá àṣálà sí abẹ́ ìbòji mi; ṣùgbọ́n tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ìná jáde láti inú igi ẹ̀gún kí ó sì jó àwọn igi Kédárì àti ti Lẹ́bánónì run!’