Judges 9:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn lónìí, ẹ dìde sí ìdílé baba mi, ẹ sì pa aadọrin àwọn ọmọkunrin rẹ̀ lórí òkúta, ẹ wá fi Abimeleki, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ̀ jọba lórí ìlú Ṣekemu, nítorí pé ó jẹ́ ìbátan yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin si dide si ile baba mi li oni, ẹnyin si pa awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ãdọrin enia, lori okuta kan, ẹnyin si fi Abimeleki, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ̀ jẹ́ ọba lori awọn Ṣekemu, nitoriti arakunrin nyin ni iṣe;)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ṣùgbọ́n lónìí ẹ̀yin ṣọ̀tẹ̀ sí ilé baba mi, ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ẹ ti pa àwọn àádọ́rin ọmọ rẹ̀, ẹ̀yin sì ti fi Ábímélékì ọmọ ẹrú-bìnrin rẹ̀ jọba lórí àwọn ènìyàn Ṣékémù nítorí tí ó jẹ́ arákùnrin yín.