Judges 9:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ẹ̀san pípa tí Abimeleki pa àwọn aadọrin ọmọ baba rẹ̀ ati ẹ̀jẹ̀ wọn lè wá sórí Abimeleki, ati àwọn ará ìlú Ṣekemu tí wọ́n kì í láyà láti pa wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ìwa-ìka ti a ti hù si awọn ãdọrin ọmọ Jerubbaali ki o le wá, ati ẹ̀jẹ wọn sori Abimeleki arakunrin wọn, ẹniti o pa wọn; ati sori awọn ọkunrin Ṣekemu, awọn ẹniti o ràn a lọwọ lati pa awọn arakunrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run ṣe èyí láti gbẹ̀san àwọn ìwà búburú, àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àwọn àádọ́rin (70) ọmọ Jérúbù-Báálì lára Ábímélékì arákùnrin wọn àti lára àwọn ènìyàn Ṣékémù, ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti pa àwọn arákùnrin rẹ̀.