Judges 9:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn eniyan ìyá rẹ̀ bá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní etígbọ̀ọ́ gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu, wọn sì gbà láti tẹ̀lé Abimeleki tayọ̀tayọ̀. Wọ́n ní, “Arakunrin wa ni Abimeleki jẹ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn arakunrin iya rẹ̀ si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi nitori rẹ̀ li etí gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu: àiya wọn si tẹ̀ si ti Abimeleki; nitori nwọn wipe, Arakunrin wa ni iṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ èyí ní etí àwọn ará Ṣékémù, ọkàn wọn fà sí àti tẹ̀lé Ábímélékì torí, wọ́n sọ wí pé, “Arákùnrin wa ní í ṣe.”