Judges 9:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ranṣẹ sí Abimeleki ní Aruma, ó ní, “Gaali, ọmọ Ebedi, ati àwọn arakunrin rẹ̀ ti dé sí Ṣekemu, wọn kò sì ní gbà fún ọ kí o wọ ibí mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si rán awọn onṣẹ ìkọkọ si Abimeleki, wipe, Kiyesi i, Gaali ọmọ Ebedi ati awọn arakunrin rẹ̀ wá si Ṣekemu; si kiyesi i, nwọn rú ilú na sokè si ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó ránṣẹ́ sí Ábímélékì pé, “Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá láti máa gbé ní Ṣékémù ṣùgbọ́n, wọ́n ń rú àwọn ènìyàn sókè láti sọ̀tẹ̀ sí ọ.