Judges 9:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ilẹ̀ bá ti mọ́, tí oòrùn sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ, gbéra, kí o sì gbógun ti ìlú náà. Nígbà tí Gaali ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá sì jáde sí ọ, mú wọn dáradára, kí o sì ṣe ẹ̀tọ́ fún wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, li owurọ̀, lojukanna bi õrùn ba si ti là, ki iwọ ki o dide ni kùtukutu owurọ̀, ki iwọ ki o si kọlù ilu na: si kiyesi i, nigbati on ati awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ ba jade tọ̀ ọ, nigbana ni ki iwọ ki o ṣe si wọn bi iwọ ba ti ri pe o yẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù bí oòrùn ti ń yọ ìwọ yóò wọ inú ìlú náà lọ láti bá a jà. Yóò sì ṣe nígbà tí Gáálì àti àwọn ogun rẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá jáde sí ọ láti bá ọ jà, ìwọ yóò ṣe ohunkóhun tí o bá fẹ́ sí wọn.”