Judges 9:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Sebulu dá a lóhùn, pé, “Gbogbo ẹnu tí ò ń fọ́n pin, tabi kò pin? Ṣebí ìwọ ni o wí pé, ‘Kí ni Abimeleki jẹ́ tí a fi ń sìn ín.’ Àwọn tí ò ń gàn ni wọ́n dé yìí, yára jáde kí o lọ gbógun tì wọ́n.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Sebulu wi fun u pe, Nibo li ẹnu rẹ wà nisisiyi, ti iwọ fi wipe, Tani Abimeleki, ti awa o fi ma sìn i? awọn enia ti iwọ ti gàn kọ́ ni iwọnyi? jọwọ jade lọ, nisisiyi, ki o si bà wọn jà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ṣébúlù dá a lóhùn pé, “Níbo ni ẹnu tí ó ń ṣe ni wà báyìí. Ṣe bí o wí pé, ‘Ta ni Ábímélékì tí àwa ó fi máa sìn ín?’ Àwọn ẹni tí ó gàn án kọ́ nìyí? Jáde lọ kí o sì bá wọn jà!”