Judges 9:43 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó kó àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ó pín wọn sí ìsọ̀rí mẹta, wọ́n sì ba níbùba ninu pápá. Bí ó ti rí i pé àwọn eniyan náà ń jáde bọ̀ láti inú ìlú, ó gbógun tì wọ́n, ó sì pa wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si mu awọn enia, o si pín wọn si ipa mẹta, o si ba ninu oko: o si wò, si kiyesi i, awọn enia nti ilu jade wá; on si dide si wọn, o si kọlù wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀, ó pín wọn sí ẹgbẹ́ mẹ́ta ó sì sá pamọ́ sí inú oko. Nígbà tí ó sì rí tí àwọn ènìyàn náà ń jáde kúrò nínú ìlú, ó dìde ó gbógun tì wọ́n.