Judges 9:48 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Abimeleki bá lọ sí òkè Salimoni, òun ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó mú àáké kan lọ́wọ́, ó fi gé ẹrù igi kan jọ, ó gbé e lé èjìká, ó sì sọ fún àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pé, “Ẹ yára ṣe bí ẹ ti rí mi tí mo ṣe.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abimeleki si gùn ori òke Salmoni lọ, on ati gbogbo enia ti o wà pẹlu rẹ̀; Abimeleki si mu ãke kan li ọwọ́ rẹ̀, o si ke ẹka kan kuro lara igi, o si mú u, o si gbé e lé èjika rẹ̀, o si wi fun awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ pe, Ohun ti ẹnyin ri ti emi ṣe, ẹ yára, ki ẹ si ṣe bi emi ti ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gun òkè Sálímónì lọ. Ó gé àwọn ẹ̀ka díẹ̀ pẹ̀lú àáké, ó gbé àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí sí èjìká rẹ̀. Ó sọ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe ohun tí ẹ rí tí mo ń ṣe yìí ní kíákíá.”