Judges 9:51 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ilé ìṣọ́ kan tí ó lágbára wà ninu ìlú náà, gbogbo àwọn ará ìlú sá lọ sinu rẹ̀, atọkunrin, atobinrin. Wọ́n ti ara wọn mọ́ inú rẹ̀, wọ́n sì gun òkè ilé ìṣọ́ náà lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ile-ẹṣọ́ ti o lagbara wà ninu ilu na, nibẹ̀ ni gbogbo awọn ọkunrin ati awọn obinrin, ati gbogbo awọn ẹniti o wà ni ilu na gbé sá si, nwọn si fara wọn mọ́ ibẹ̀; nwọn si gòke ile-ẹṣọ́ na lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ilé ìṣọ́ kan tí ó ní agbára sì wà nínú ìlú náà. Gbogbo àwọn ènìyàn ìlú náà ọkùnrin àti obìnrin sá sínú ilé ìṣọ́ náà. Wọ́n ti ara wọn mọ́ ibẹ̀ wọ́n sì sá lọ sí inú àjà ilé ìṣọ́ náà.